Home Community Iroyin Ipade Ti O Waye Ni Afin Oba Olumoyegun, Oniju Ilu Iju-Odo
Community - Press Releases - 1 week ago

Iroyin Ipade Ti O Waye Ni Afin Oba Olumoyegun, Oniju Ilu Iju-Odo

IROYIN IPADE TI O WAYE NI OJO KOKANDINLOGUN OSU KESAN ODUN 2021 , NI AFIN OBA OLUMOYEGUN , THE ONIJU ILU IJU-ODO

IBERE IPADE
Ipade bere ni agogo merin pelu adura lati enu Ogbeni Akinwumi Oluwarimi.

IKINI KAABO ALAGA

Gege bi asa re, Alaga Egbe Eni Owo Lord Isaac ki omo egbe kaabo si ipade.
Laijafara, Alaga dupe lopolopo fun ifarada Kabiyesi Oba Oniju fun fi fi wa lokan bale ni wakati ti a fii unduro de omo egbe nitori idaduro ti o waye nipa ojo aragba bu ti o sele ni akoko ti o ye ki ipade ti bere sehin.

Alaga te siwaju lati fi idi abajo Egbe ati ise wa han fun awon eniyan wa tuntun lati Ilu Iju Odo ati awon asoju Ikale lati Ilu Ayede ni Ipinle Ogun State. Won dupe lopolopo fun wiwa si ipade asepo Ikale gbogbo yi.

Saaju si Alaga pe akiyesi ijoko si idaduro Omo Egbe ti aroiroda ojo ti onlo lowo. Ni idi eyi, won gbawa niyanju ki a fi akoko wa jiroro lori ohun kan soso ti o se koko lakoko yi.
Eyi ni lati soro lori oro abo ile Ikale ati eto asepapo Egbe Omo Ikale lehin Okun pelu Egbe wa lori oro abo Ile Ikale ti yio waye ni ojo ketadinlogun Osu kesan ni ibugbe Jagunjagun afehinti Omoba, Olu Bajowa Oloye Jagunmolu Ile Ikale.

KIKA AKOSILE IPADE TO KOJA
Akowe Egbe Ogbeni Oguniyi Adetoye woye wipe ese ipade ko pe, ni idi eyi Egbe fenuko pe ki a fi kika akosile sile di ipade osu kewa Odun.

OBA ONIJU KI EGBE
Kabiyesi HRM Oba Olumoyegun, The Oniju of Iju Odo, fi tayoatayo ki Egbe. Oba sure tokantokan fun apejopo egbe yi. Oba fi to wa leti pe Egbe yi ni asaro itesiwaju ti o je ekini iru re in ile Ikale ti oun se opolopo akitiyan lati ri pe asepo gbogbo Ikale ni orilede gbogbo parapo wa si isokan ti o yan manran lati tan imole ile Ikale si gbogbo agbaye.
Oba tesiwaju lati ki awon asoju Ikale lati ilu Ayede ni Ipinle Ogun State.
Won dupe gidigidi fun jije ipe Egbe yi lati ri pe Ikale ni Orilede Naijiria parapo lati fimo sokan fun idagba soke ile Ikale ati Omo Ikale kaakiri agbaye.
Ni ipari oro won, Kabiyesi dupe lopolope lowo Alaga Egbe ati awon igbimo re fun gbogbo igboke gbodo re lati rii pe atunto ise wa ati itesiwaju ile Ikale di ohun amuyangan.
Oba je ki o di mimo fun Egbe pe awon wa lehin wa ati ni igba kiigba ti Egbe ni iranlowo lati bere lodo won pe awon setan lati se ohun to to.
Oba se adura atokan wa latori ite fun itesiwaju Egbe ati gbogbo igbimo akoso egbe.
Lakotan, Kabiyesi fi orisiri otin oyinbo ati opolopo obi abata pelu akara oyinbo ki Egbe kaabo si afin.

ORO ETO ABO ( I S O )
Laifi akoko sofo, Alaga fi to ipade leti pe erongba okan wa nipa oro abo to daju ni ile Ikale ti a tii se asaro lori re fun igba dia yio waye ni ojo Ketadinlogun osu kesan, ni ibugbe ajagunfehinti Omoba Olu Bajowa ni Ilu Igbotako.
Alaga je ko di mimo pe
eto abo yi yio waye nipa ifowosowopo Egbe Omo Ikale merin otooto ni oke Okun pelu Egbe wa ni ile.

Wonyi ni awon Egbe lati oke okun:
Ikale World Congress USA ,
Egbe Omo Ikale U K & Ireland
Irele Progressive Union (USA)
Ikale Association of Canada .
Alaga fi to ijoko leti pe gbogbo Oba Alade ile Ikale titi lo de Ogun State ati awon Oloja gbogbo pelu awon oga gbofinro Olopa ati awon eka abo ijoba gbogbo ni a ti fi iwe pe.

IKINI AWON ASOJU IKALE LATI AYEDE OGUN STATE
Adele Oba Ilu Ayede, Oloye Giga Adesote Olamoju ti o wa pelu Oloye Giga Obienodi Sara of Ayede, ki Kabiyesi Oniju ati gbogbo ijoko.

Adele Oba na dupe lopolopo fun ero rere ti Egbe ni lokan lati rii pe gbogbo Ikale ni orile aye wa ni isokan.

Won jise pe Kabiyesi HRM Adegboyega Adesore JP, The Olorofun Lemegha of Ayede fi ohun adura itesiwaju Egbe ati Ikale lapapo ranse.

Won fi da ni loju pe awon ko ni fa sehin nipa asepo Ikale ni gbogbo ona.
Lakotan, won fi ye wa pe awon setan ni igba kugba ti Egbe ba lero lati gbe ipade wa si Ayede pe awon koni fa sehin lati gbawa lalejo.

Bakana won fi dawaloju pe awon yio gbe igbese to ye latise nipa oro abo gbogbo ile Ikale nitoripe won mo pe akoko ti orilede wa wa yi ko rorun rara nipa abo eniyan ati agbegbe wa gbogbo.

ABA MIMU IPADE SI IPAMO
Aba waye ni deede agogo mefa lati enu Arakunrin Adetoye Ogunniyi ti Ogbeni Oladema Sesan sin ki aba na lehin.

Ni idi eyi a mu ipade wa si ipamo pelu adura oore ofe lapapo.

Ipade timbo yio waye ni afin Adele Oba (Regent) Ode Irele, High Chief Olarewaju Ayeromara, ni ojo ketadinlogun osu kewa odun.

 

OGUNNIYI ADETOYE

AKOWE EGBE

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

The Kingdom of Benin

The Kingdom of Benin prospered from the 1200s to the 1800s C.E. in western Africa, in what…